Isaiah 18:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo aráyé, ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè, ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ẹnyin ti ngbe aiye, ati olugbé aiye, ẹ wò, nigbati on gbe ọpagun sori awọn oke giga; ati nigbati on fọn ipè, ẹ gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ.