Isaiah 18:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé OLUWA sọ fún mi pé òun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òun bí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan, ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bẹ̃li Oluwa sọ fun mi, emi o simi, emi o si gbèro ninu ibugbé mi, bi oru ọsángangan, ati bi awọsanma ìri, ninu oru ikorè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè.”