Isaiah 18:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè, lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso, tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀, ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà, yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ṣaju ikorè, nigbati ìrudi ba kún, ti itanná ba di eso-àjara pipọn on o fi dojé rẹ́ ẹka-titun, yio si mu kuro, yio si ke ẹka lu ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí, kí ìkóórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìtànná kò sí mọ́, nígbà tí ìtànná di èso tí ó ń pọ́n bọ̀. Òun yóò sì fi ọ̀bẹ ìwẹgi gé àwọ ìsó tuntun kúrò, yóò sì gé àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbilẹ̀ lulẹ̀ a sì kó wọn dànù.