Isaiah 18:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀, wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè, ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́. Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si fi wọn silẹ fun awọn ẹiyẹ oke-nla, ati fun awọn ẹranko aiye: awọn ẹiyẹ yio yá õrùn lori wọn, gbogbo awọn ẹranko aiye yio si potutù lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọn la ó fi lé àwọn jẹran jẹran ẹyẹ lọ́wọ́ lórí òkè àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣoúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.