Isaiah 19:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí: OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti. Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀RỌ-ìmọ niti Egipti. Kiyesi i, Oluwa ngùn awọsanma ti o yara, yio si wá si Egipti: a o si ṣi ipò awọn òriṣa Egipti pàda niwaju rẹ̀, aiya Egipti yio yọ́ li ãrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Éjíbítì: Kíyèsíi, OLÚWA gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́sin ó sì ń bọ̀ wá sí Éjíbítì. Àwọn ère òrìṣà Éjíbítì wárìrì níwájúu rẹ̀, ọkàn àwọn ará Éjíbítì sì ti domi nínú un wọn.