Isaiah 19:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn, wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀, bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ti mí ẽmi iyapa si inu rẹ̀ na: nwọn si ti mu Egipti ṣina ninu gbogbo iṣẹ inu rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀muti enia ti nta gbọngbọ́n ninu ẽbi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ti da ẹ̀mí òòyì sínú un wọn; wọ́n mú Éjíbítì ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n nínú èébì i rẹ̀.