Isaiah 19:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.