Isaiah 19:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun. Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni ilu marun ni ilẹ Egipti yio fọ̀ ède Kenaani, ti nwọn o sì bura si Oluwa awọn ọmọ-ogun; a o ma pè ọkan ni Ilu ìparun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.