Isaiah 19:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti, olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà, àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà, ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji, ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si gbe Egipti dide si Egipti: olukuluku yio si ba arakunrin rẹ̀ jà, ati olukuluku aladugbò rẹ̀; ilu yio dojukọ ilu, ati ijọba yio dojukọ ijọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò rú àwọn ará Éjíbítì sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládúgbò yóò dìde sí aládúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.