Isaiah 19:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si jẹ fun ami, ati fun ẹ̀ri si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ Egipti: nitori nwọn o kigbe pè Oluwa nitori awọn aninilara, yio si rán olugbala kan si i, ati ẹni-nla, on o si gbà wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLÚWA nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.