Isaiah 19:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio si di mimọ̀ fun Egipti, awọn ara Egipti yio so mọ́ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si rú ẹbọ, nwọn o si ta ọrẹ; nitõtọ nwọn o jẹ'jẹ fun Oluwa, nwọn o si mu u ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Éjíbítì àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba OLÚWA gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ oníhóró, wọn yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLÚWA wọn yóò sì mú un ṣẹ.