Isaiah 19:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa o si lù Egipti bolẹ, yio si mu u li ara da: nwọn o si yipada si Oluwa, on o si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn, yio si mu wọn li ara da.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn kan bá Éjíbítì jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí OLÚWA, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.