Isaiah 19:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni opopo kan yio wà lati Egipti de Assiria, awọn ara Assiria yio si wá si Egipti, awọn ara Egipti si Assiria, awọn ara Egipti yio si sìn pẹlu awọn ara Assiria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Ásíríà yóò lọ sí Éjíbítì àti àwọn ará Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Éjíbítì àti ará Ásíríà yóò jọ́sìn papọ̀.