Isaiah 19:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti, n óo sọ ète wọn di òfo. Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹ ati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹmi Egipti yio si rẹ̀wẹsi lãrin inu rẹ̀; emi o si pa ìmọ inu rẹ̀ run: nwọn o si wá a tọ̀ òriṣa lọ, ati sọdọ awọn atuju, ati sọdọ awọn ajẹ́, ati sọdọ awọn oṣó;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀.