Isaiah 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, ati àwọn ọlọ́kàn gíga, ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan nípamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀sílẹ̀),