Isaiah 2:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta, wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ, nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA, ati ògo ọlá ńlá rẹ̀ nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si wọ̀ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ìbẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀, nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà OLÚWA àti ògo ọlá ńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.