Isaiah 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù, ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ. Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na, enia yio jù òriṣa fadakà rẹ̀, ati òriṣa wurà rẹ̀, ti nwọn ṣe olukuluku wọn lati ma bọ, si ekute ati si àdan,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò má a sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán,