Isaiah 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé: “Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ, kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀, kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn ó si sọ pé “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ sí òkè OLÚWA, sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Síhónì wá, àti ọ̀rọ̀ OLÚWA láti Jérúsálẹ́mù wá.