Isaiah 2:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí. Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀ wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀ èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀ èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.