Isaiah 2:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù, àní, ìdílé Jakọbu. Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn, àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini, Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jákọ́bù. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ó ti ìlà oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Fílístínì wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà