Isaiah 20:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li ọba Assiria yio kó awọn ara Egipti ni igbèkun ati awọn ara Etiopia ni igbèkun, ọmọde ati arugbo, nihòho ati laibọ̀ bàta, ani ti awọn ti idí wọn nihòho, si itiju Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Áṣíríà yóò kó àwọn ìgbèkùn Éjíbítì lọ ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kúṣì, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí goloto—bí àbùkù Éjíbítì.