Isaiah 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olugbé àgbegbe okun yio si wi li ọjọ na pe, Kiyesi i, iru eyi ni ireti wa, nibiti awa salọ fun iranlọwọ ki a ba le gbani là kuro li ọwọ́ ọba Assiria: ati bawo li a o si ṣe salà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbọ́kànlé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Ásíríà! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”