Isaiah 21:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà, ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.