Isaiah 21:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí, gbogbo ara ní ń ro mí bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan, wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú èyí, ìrora kómi lára gírígírí, ìrora gbámimú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, Mo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòrúúrù nípa ohun tí mo rí.