Isaiah 21:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣin tí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí i tí àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí àwọn kan gun ràkúnmí, kí ó fara balẹ̀ dáradára, kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn agun-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ràkúnmí, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.”