Isaiah 21:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀, wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!” “Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó! Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀, ó ti wó lulẹ̀ patapata.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin. Ó sì mú ìdáhùn padà wá: ‘Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ ló fọ́nká lórí ilẹ̀!’”