Isaiah 22:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé: “A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín títí tí ẹ óo fi kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mímọ̀ létíì mi: “Títí di ọjọ́ ikúu yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni OLÚWA wí, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.