Isaiah 22:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?