Isaiah 22:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun yóò ká ọ rúgúdú bí i bọ́ọ̀lù yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀ èdè ńlá kan. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!