Isaiah 22:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ogo ile baba rẹ̀ ni nwọn o si fi kọ́ ọ li ọrùn, ati ọmọ ati eso, gbogbo ohun-elò ife titi de ago ọti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ògo ìdílée rẹ̀ ni yóò rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ gbogbo ohun èlò aláìlágbára láti orí abọ́ rẹ̀ dé orí ìdẹ̀ rẹ̀.