Isaiah 22:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Li ọjọ na, ni a o ṣi iṣó ti a kàn mọ ibi ti o le ni ipò, a o si ke e lu ilẹ, yio si ṣubu; ẹrù ara rẹ̀ li a o ké kuro: nitori Oluwa ti sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní àyèe rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lóríi rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.