Isaiah 22:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká, pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Élámù mú àpò-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, kírí yọ apata rẹ̀ síta.