Isaiah 23:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí: Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi; nítorí pé Tire ti di ahoro, láìsí ilé tabi èbúté! Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀RỌ-ìmọ niti Tire. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi; nitoriti a o sọ ọ di ahoro, tobẹ̃ ti kò si ile, kò si ibi wiwọ̀: a fi hàn fun wọn lati ilẹ Kittimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè: Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì! Nítorí a ti pa Tírè run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.