Isaiah 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì, àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìí Àwọn Ásíríà ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.