Isaiah 23:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè: