Isaiah 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, OLÚWA yóò bá Tírè jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.