Isaiah 23:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọjà rẹ̀ ati ọ̀ya rẹ̀ yio jẹ mimọ́ si Oluwa: a kì yio fi ṣura, bẹ̃li a ki yio tò o jọ; nitori ọjà rẹ̀ yio jẹ ti awọn ti ngbe iwaju Oluwa, lati jẹ ajẹtẹrùn, ati fun aṣọ daradara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èree rẹ̀ àti owó iṣẹ́ẹ rẹ̀ ni a ó yà ṣọ́tọ̀ fún OLÚWA; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú OLÚWA, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.