Isaiah 23:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoni nítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní: “N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ; n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà rí kì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọ àní ìwọ ilé-ààbò ti òkun, nítorí òkun ti sọ̀rọ̀: “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”