Isaiah 23:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire, Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé? Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀; gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ló gbérò èyí sí Tírè, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládé tí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?