Isaiah 24:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn, wọ́n ń fi ògo fún Olódodo. Ṣugbọn èmi sọ pé: “Mò ń rù, mò ń joro, mò ń joro, mo gbé! Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀, wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati opin ilẹ li awa ti gbọ́ orin, ani ogo fun olododo. Ṣugbọn emi wipe, Iparun mi, iparun mi, egbé ni fun mi! awọn ọ̀dalẹ ti dalẹ: nitõtọ, awọn ọ̀dalẹ dalẹ rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!” “Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”