Isaiah 24:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá, yóo já sinu kòtò, ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtò yóo kó sinu tàkúté. Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí, àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, ẹniti o sá kuro fun ariwo ìbẹru yio jin sinu ọ̀fin; ati ẹniti o jade lati inu ọ̀fin wá li a o fi ẹgẹ́ mu: nitori awọn ferese lati oke wá ṣi silẹ, ipilẹ ilẹ si mì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹkùn yóò gbámú. Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀ Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.