Isaiah 24:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa; ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀; ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀; ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà. Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówó ni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó. Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi o ti ri fun awọn enia, bẹ̃li o ri fun alufa; bi o ti ri fun iranṣẹ-kunrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun iranṣẹbinrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun olùra, bẹ̃ni fun olùta; bi o ti ri fun awinni, bẹ̃ni fun atọrọ; bi o ti ri fun agbà elé, bẹ̃ni fun ẹniti o san ele fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbésè.