Isaiah 24:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òṣùpá yóo dààmú, ìtìjú yóo sì bá oòrùn. Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọba lórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu. Yóo sì fi ògo rẹ̀ hàn níwájú àwọn àgbààgbà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li a o dãmu oṣupa, oju yio si tì õrun, nigbati Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jọba li oke Sioni, ati ni Jerusalemu, ogo yio si wà niwaju awọn alàgba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti òòrùn; nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò jọba ní orí òkè Ṣíhónì àti ní Jérúsálẹ́mù, àti níwájú àwọn alàgbà rẹ ní ògo.