Isaiah 24:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ. Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀, eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.