Isaiah 25:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi. N óo gbé ọ ga: n óo yin orúkọ rẹ. Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu, o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́, o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA, iwọ li Ọlọrun mi; emi o gbe ọ ga, emi o yìn orukọ rẹ; nitori iwọ ti ṣe ohun iyanu; ìmọ igbani, ododo ati otitọ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, ìwọ ni Ọlọ́run un mi; Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọọ̀ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèròo rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.