Isaiah 25:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si nà ọwọ́ rẹ̀ jade li ãrin wọn, gẹgẹ bi òmùwẹ̀ iti nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati wẹ̀: on o si rẹ̀ igberaga wọn silẹ pọ̀ pẹlu ikogun ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn.