Isaiah 25:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka, ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro. Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò, ati ìbòòji ninu oòrùn. Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiri bẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri