Isaiah 25:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni oke-nla yi li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sè asè ohun abọ́pa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ori òkè yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèṣè àṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnì tí ó gbámúṣé.