Isaiah 26:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà, orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé: “A ní ìlú tí ó lágbára, ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Júdà: Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀.