Isaiah 26:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún, kí ojú sì tì wọ́n. Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀ta rẹ jó wọn run.